HYMN 179

C.M.S. 63 A & M. 50 L.M (FE 197) 
“Emi o si tun pada wa" - John 14:3



1.  LEBA Odo Jordani ni, 

     Onibaptist nke wipe 

     Oluwa mbo! Oluwa mbo! 

     E gbo ‘hin ayo: Oba mbo.


2.  K'ese tan ni gbogbo okan 

     K’olorun ba le ba wa gbe 

     K'a pa ile okan wa mo

     Ki Alejo-nla yi to de.


3.  Jesu. lwo ni igbala

     Esan ati Alabo wa: 

     B‘itanna l’awa ‘ba segbe 

     Bikose l‘ore-ofe Re.


4.  S’awotan awon alaisan 

     Gb’elese to subu dide 

     Tanmole Re ka ‘bi gbogbo 

     Mu ewa aiye bo s’ipo.


5.  K’a f’iyin f’Omo Olorun 

     Bibo Eni mu ‘dande wa;

     Enit’ a sin pelu Baba 

     At’Olorun Emi Mimo.  Amin

English »

Update Hymn