HYMN 178

(FE 196)
Tune: m.r.d.s.d.r.m,
"Kiyesi, O mbo ninu awosanma” - Ifi. 1:7



1.  lWO mbo wa, Oluwa 

     lwo mbo wa, Oba mi 

     Ninu ‘tansan ewa Re

     Ni titayo Ogo re 

     Mura de, mura de.

Egbe:  Oko 'yawo f'ere de;

            L'oru ni igbe yio ta,

            Mura l'o ko okan mi.


2.  Wundia to s’oloto

     Ti mura nigbagbogbo 

     Igba ayo sunmole

     lgba awe y‘odopin. 

Egbe:  Oko 'yawo f'ere de...


3.  lwo mbo wa nitoto

     A o pade Re lona

     A o ri O, a mo O,

     Ni ‘dapo mimo julo. 

Egbe:  Oko 'yawo f'ere de...


4.  Wura ko ni le gba O, 

     Ohun asan l‘oro je 

     lgbagbo ti ko mira

     Ni y'o gb‘ade nikehin.

Egbe:  Oko 'yawo f'ere de...


5.  Wundia mewa l’a yan 

     Marun pere lo yege 

     Marun ko ni ororo 

     lna emi won ti ku.

Egbe:  Oko 'yawo f'ere de...


6.  ‘Binu Re tobi pupo

     Si awon t’o gbagbe Re 

     Ewure apa osi

     L’ao se won nikehin 

Egbe:  Oko 'yawo f'ere de...


7.  Jowo se wa l‘ayanfe,

     Ki a le ba O joba

     Angeli l‘ao ba kegbe

     Ti a o gbe aiku wo.

Egbe:  Oko 'yawo f'ere de;

            L'oru ni igbe yio ta,

            Mura l'o ko okan mi.  Amin

English »

Update Hymn