HYMN 173

H.C. 57 D. &s (FE 191)
"Eniti nfi ekun rin lo, ti o si gbe
irugbin Iowo, loto yio fi ayo pada 
wa, yio si ru iti re" - Ps. 126:6



1.  Wa, enyin olope wa, 

     Gbe orin ikore ga

     Ire gbogbo ti wole 

     K'otutu oye to de 

     Olorun Eleda wa 

     L'o ti pese f’aini wa 

     Wa k‘a re ‘le Olorun 

     Gbe orin ikore ga.


2.  Oko, Olorun l'aiye 

     Lati s'eso iyin Re 

     Alikama at'epo 

     Ndagba f'aro tab‘ayo 

     Ehu na. ipe tele

     Siri oka nikehin 

     Oluwa ‘kore, mu wa 

     Je eso rere fun O.


3.  N’tori Olorun wa mbo 

     Y’o si kore Re s’ile 

    On o gbon gbogbo panti 

    Kuro I’oko Re n’jo na

    Y’o f’ase f’awon Angeli 

    Lati gba epo s’ina

    Lati ko alikama 

    Si aba Re titi lai.


4.  Beni, ma wa, Oluwa

     Si ikore ikehin

     Ko awon enia Re jo 

     Kuro l’ese at’ aro

     So won di mimo lailai 

     Ki nwon le ma ba O gbe; 

     Wa t’iwo t’Angeli Re, 

     Gbe orin ikore ga.  Amin

English »

Update Hymn