HYMN 170

7s (FE 188) 
Tune: Eje ka finu didun 
"Eniti o nfi onje fun eda gbogbo nitori
anu re duro Iailai" - Ps. 136:25



1.  YIN Oluwa Oba ‘wa 

     Egbe ohun iyin ga

     Anu re o titi 

    Lododo dajudaju.


2.  Yin Enit’ o da orun 

     Ti o nran l‘ojojumo 

     Anu re o wa titi 

     Lododo dajudaju.


3.  Ati osupa l'oru

    Ti o ntanmole jeje 

    Anu re o wa titi 

    Lododo dajudaju.


4.  Yin Enit’o nm‘ojo ro, 

     T‘o nmu irugbin dagba 

     Anu re o wa titi 

     Lododo dajudaju.


5.  Enit’o pase fun ‘le 

     Lati mu eso po si 

     Anu re o wa titi 

     Lododo dajudaju.


6.  Yin fun ikore oko

     O mu ki a ka wa kun; 

     Anu re o wa titi 

     Lododo dajudaju.


7.  Yin f‘onje t'o ju yi lo, 

     Eri ‘bukun ailopin 

     Anu re o wa titi 

     Lododo dajudaju.


8.  Ogo f 'Oba olore

     Ki gbogbo eda gberin

     Ogo fun Baba, Omo

     At’ Emi: Metalokan.  Amin

English »

Update Hymn