HYMN 169

S.S. & S417 (FE 187)
Tune: Anu Re Oluwa lawa ntoro 
"Anu Re po de orun" - Ps. 57:10



1.  OLUWA awa omo Re tun de 

     Lati wa anu re.

     Ni ajodun isin Ikore wa, 

     Masai senu fun wa.

Egbe:  Anu! Anu! Anu la nfe 

           Iowo Re

           Baba wa orun

           Jo si ferese Orun Re loni 

           Rojo anu le wa.


2.  Jesu Oluwa l’ojo aiye Re 

     Oba ‘lanu ni O

     Awon adete ati afoju 

     R'anu gba lowo Re

Egbe:  Anu! Anu! Anu...

3.  Lodun yi, Oluwa awa mbe o 

     Ma jek' ise won wa

     K’O si je k'a s’owo b’ode p’ade 

     K'ara de gbogbo wa.

Egbe:  Anu! Anu! Anu...


4.  Mase je ki esu ri wa gbe se 

     Ni gbogb’ ojo aiye wa;

     Ko si ti 'lekun iku at'arun

     Mu wa di amodun.

Egbe:  Anu! Anu! Anu...

5.  Oluwa, dari ese wa ji wa 

     T’a fi bi O ninu

     Jo se ayipada rere fun wa 

     K‘a le ma je Tire.

Egbe:  Anu! Anu! Anu...


6.  Nigbat’ikore aiye ba pari 

     T'a ko awa na jo

     B’ikore sinu aba Re orun 

     F’ anu tewogba wa.

Egbe:  Anu! Anu! Anu la nfe 

           Iowo Re

           Baba wa orun

           Jo si ferese Orun Re loni 

           Rojo anu le wa.  Amin

English »

Update Hymn