HYMN 168

1.  L’ORI oke Sion t’o ga j‘orun lo 

     N’ilu ‘yanu t’o l‘ewa pupo 

     Nigboose emi si lo si ilu naa 

     Tori mo n to sura mi sibe.

Egbe:  Mo n to isura mi si orun I'oke

           N'ilu t’o dara, ilu ewa

           Gba t’a ba r’ogo Re, n o ni ere pupo 

           Tori mo n to sura mi sibe.


2.  Mo gbo pe le kan n be f’awon eni mimo 

     Ti Olugbala ti lo pese

     Ita re je wura, at’ opopo wura

     Emi n to isura mi sibe.

Egbe:  Mo n to isura mi si...


3.  Gbogbo ife okan ati agbara mi 

     At’ise ti mo n se pelu Re

     Wonyi yoo je oro ti n o ri n’ikehin 

     Tori mo n to sura mi sibe.

Egbe:  Mo n to isura mi si...


4.  Bi mo tile n kiri bi alaini laye 

     N'nu sona at'adura gbogbo

     Laipe n o gbo ipe ayo lati re le 

     Tori mo n to sura mi Sibe.

Egbe:  Mo n to isura mi si orun I'oke

           N'ilu t’o dara, ilu ewa

           Gba t’a ba r’ogo Re, n o ni ere pupo 

           Tori mo n to sura mi sibe.  Amin

English »

Update Hymn