HYMN 16

P.B. C.M.S 23, 9s 8s (FE33)
"Ise won ni lati duro lororo lati
dupe, ati lati yin Oluwa, ati be 
gege Ii asale” - 1 Kron. 23:30


1.  OLUWA, ojo t'o fun wa pin

     Okunkun si de l‘ase Re, 

     ‘Wo l'a korin owuro wa si, 

     lyin Re y'o m'ale wa dun.


2.  A dupe ti Ijo Re ko nsun, 

     B’aiye ti nyi lo s'imole

     O si nsona ti gbogbo aiye 

     Ko simi tosan-toru.


3.  B'ile si ti mo lojujumo 

     Ni orile at'ekusu

     Ohun adura ko dake ri, 

     Be l’orin iyin ko dekun.


4.  Orun t‘o wo fun wa, si ti la 

     S‘awon eda iwo-orun 

     Nigbakugba li enu si nso 

     lse ‘yanu Re di mimo.


5.  Be, Oluwa, lai n’ijoba Re, 

     Ko dabi aiye

     O duro, o si nse akoso

     Tit' eda Re o juba Re.  Amin


English »

Update Hymn