HYMN 156

A & M. 212. 8.8.6 (FE 175)
“Olutunu na, ti se Emi Mimo, on ni o ko
nyin li ohun gbogba" - John 14:26



1.  SI O olutunu Orun

     Fun ore at'agbara Re,

     A nko Alleluya.


2.  Si O, ife enit‘ o wa,

     Ninu Majemu Olorun

     A nko Alleluya.


3.  Si O ohun eniti npe 

     Asako kuro ninu ese, 

     A nko Alleluya.


4.  Si O, agbara eniti

     O nwe ni mo, t'o nwo ni san 

     A nko Alleluya.


5.  Si O, ododo Eniti 

     Gbogbo ileri Re je ti wa 

     A nko Alleluya.


6.  Si O, Oluko at’Ore 

     Amona wa toto d’opin 

     A nko Alleluya.


7.  Si O, Eniti Kristi ran

     Ade on gbongbo ebun Re, 

     A nko Alleluya.


8.  Si O, Enit’o je okan 

     Pelu Baba ati Omo

     A nko Alleluya.  Amin
 

English »

Update Hymn