HYMN 148

D7S6S



1.  IMOLE iyanu ntan

     Gba Kristien ba nkorin 

     Oluwa ni ngbe ni ro 

     lwosan n'n'apa Re

     ‘Gba olutunu jin‘na 

     O nfun okan ni‘simi 

     lmole otun y'o la 

     Nigba t'ojo si da.


2.  Nigba t‘ero mimo nso 

     L‘ayo la‘wa nlepa 

     lgbala Olorun wa

     T’a si nri gba l‘otun

     O ngba wa n‘nu ‘banuje 

     Awa le f‘ayo wipe

     Je ki ola aimo de 

     Ohun t'o wun k'o je.


3.  Ohunkohun t’o le de 

     Jesu y’o gba wa la 

     On t’o wo lili l'aso 

     Y’o fi aso wo wa

     L'abe orun t‘o teju 

     Ghogbo eda l’o nbo 

     On t‘o nbo eiye orun 

    Y’o bo aw’omo Re.


4.  B'ajara tabi opoto

     Ko lati m'eso wa

     Bi gbogbo eweko gbe

     T’ agbo agutan s’egbe 

     Olorun wa mbe sibe 

     Iyin Re y’o kun enu mi 

     Bi mo gbekele E titi 

     Ayo y’o je t’emi.  Amin

English »

Update Hymn