HYMN 146

(FE 164)
“Eleda re li oko re" - Isaiah 54:5



1.  ELEDA gbogbo aiye

     Li ase Re ni

     Awa pejo loni 

     Lati yin Oko Re. 

Egbe:  A dupe Iowo Re 

           Baba Olore,

           Ki 'bukun Re orun 

           Ba le gbogbo wa.


2.  Toju wa Baba orun 

     Larin aiye wa yi 

     Pa wa mo k’o bo wa, 

     Pese f’aini wa.

Egbe:  A dupe Iowo Re...


3.  Kerubu, Serafu

     E m’okan nyin le, 

     Awa ni Baba nla 

     T'o mo edun wa. 

Egbe:  A dupe Iowo Re...


4.  Kerubu, Serafu 

     E d’amure nyin 

     E ma fi aye sile 

     Fun emi Esu.

Egbe:  A dupe Iowo Re...


5.  Enyin asaju wa,

     E ku ‘se Emi 

     Olorun alaye

     Yio wa pelu nyin. 

Egbe:  A dupe Iowo Re...


6.  Enyin Aladura 

     K'e ma gbadura 

     Metalokan y'o gbo 

     Y'o segun fun wa. 

Egbe:  A dupe Iowo Re...


7.  Gbogbo enyin agan,

     Baba yio pese 

     Enyin ti e bimo 

     Gbogbo won yio la.

Egbe:  A dupe Iowo Re...


8.  Enyin t'e si loyun

     Jah yio s’abo nyin

     Enyin t'e ko ri se 

     Jah yio pese.

Egbe:  A dupe Iowo Re 

           Baba Olore,

           Ki 'bukun Re orun 

           Ba le gbogbo wa.  Amin

English »

Update Hymn