HYMN 143

(FE 160)
“Eho iho ayo si Oluwa" - Ps. 100:1



1.  GBOGBO Egbe Onigbagbo 

     T’o wa ni gbogbo aiye 

     T‘awon to wa nigberiko

     Ko jade wa woran.

Egbe:  Ka jo ho. Halleluya! 

           F' Oba Olodumare 

           A sope a t'ope da, 

           T'o mu wa dojo oni.


2.  Gbogbo Egbe ni gbogbo Ijo,

     Ko si 'ru eyi ri

     Ti Maikieli je Balogun fun 

     Ko s’egbe to dun to. 

Egbe:  Ka jo ho...


3.  Emi Mimo lo ndari wa, 

     T'enikan ko le mo

     A f’awon t‘a firan na han 

    Lo mo ijinle re.

Egbe:  Ka jo ho...


4.  At’okunrin at’obinrin, 

     T’o wa ni Serafu 

     Egbe ogun onigbagbo 

     K’a jumo d'orin po. 

Egbe:  Ka jo ho...


5.  Aje, Oso, ko n’ipa kan 

     Lor'Egbe t’awa yi, 

     Balogun Egbe Serafu 

     Ti jagun o molu.

Egbe:  Ka jo ho...


6.  Awamaridi n'ise Re 

     T'enikan ko le mo 

     Eda aiye, eda orun 

     Ko le ridi ‘se Re. 

Egbe:  Ka jo ho...


7.  Gbogbo awon alailera 

     To wa nin ‘Egbe na; 

     Njeri si ohun ti nwon ri, 

     Oluwa lo nsabo won. 

Egbe:  Ka jo ho...


8.  Awon Egbe to wa lorun 

     Nko si Serafu t‘aiye 

     Pe ka mura ka d'owo po

     Ka jo yin Oba Ogo. 

Egbe:  Ka jo ho...


9.  Pipe, Mimo, Tito, Rere 

     Fawon to wa lorun 

     Imole itansan si ntan 

     lrawo Owuro.

Egbe:  Ka jo ho...


10.  Mimo ati Mimo julo 

       Jehovah-Jireh wa, 

       Jehovah‐Rufi yio so wa 

       Latubotan aiye wa.

Egbe:  Ka jo ho. Halleluya! 

           F' Oba Olodumare 

           A sope a t'ope da, 

           T'o mu wa dojo oni.  Amin

English »

Update Hymn