HYMN 141

S.M. (FE 158)
"Emi o ma yin Oluwa tinutinu mi" - Ps. 111:1



1.  MO f'ope f‘Oluwa 

     Ahon mi nyin Jesu

    Ti a ko ni lat’ewe wa, 

    Lati kaOro Re.


2.  B'ese mi ti po to 

     Egbe at'ewu nla 

     Eru s’ese nipa eda 

     Ni Bibeli nko mi.


3.  Bibeli l’o nko ni

     B‘a ko tile senkan; 

     Nje nibo l’elese y'o wo, 

     Lati bo n‘nu egbe?


4.  lwe Mimo Re yi,

     Jesu, Oluwa mi,

     L'o nf' ona igbala han ni, 

     L'o si nko-ni rere.


5.  Ninu re ni mo ko

     Bi Krist'Om'Olorun 

     Ti terigba iya nla wa, 

     Ti O Si ku fun wa.


6.  O gunwa li orun

     O nran Emi Re wa 

     Lati fi ife nla Re han 

     At'ilana rere.


7.  Emi Mimo, ko mi 

     K'okan mi si le gba 

     Gbogbo ‘wasu oro Re gbo 

     B’awon enia Re.


8.  Nigbana, Oluwa 

     L'orin ‘yin mi y‘o ga;

     N'tori t'a ko mi lati ka

     Bibeli mimo Re.  Amin

English »

Update Hymn