HYMN 140

(FE 157)
"Efi ope fun Oluwa" - Ps. 136:1



1.  OM'Egbe Serafu 

     At’Egbe Kerubu

     E f’ope fun Olorun wa, 

     E f'ope fun Olorun wa 

     T’iru ojo oni.

     Fi soju emi wa. 

Egbe:  E ba wa korin po,

           K’awa jumo k'AIleluya 

           Ope to ye fun Jehovah 

           Oba Onibu-Ore.


2.  Opo Elegbe wa,

     Ni ko r’ojo oni, 

     Opolopo ti sako lo 

     Idamu wa f’elomiran, 

     Opo si ti koja

     Lo si aiyeraiye.

Egbe:  E ba wa korin po...


3.  Egbe Aladura,

     E mura si adura;

     Gbe ida ‘segun nyin soke 
   
     Oluwa yio ba wa segun 

     Oto l’esu gbogun

     Ko ni le bori wa.

Egbe:  E ba wa korin po...


4.  Ninu odun tawa yi

     Agan yio gb’omo pon 

     Awon alaisan yo dide! 

     Arun ko ni ya ile wa, 

     Onirobinuje;

     Yio ri itunu gba.

Egbe:  E ba wa korin po...


5.  F‘awon ti ko r'ise 

     Baba yio pese
 
     Awon t‘ebi npa yio si yo 

     Awon t'o je ‘gbese y‘o san 

     Aini ko ni si mo

     Ayo yio kari wa. 

Egbe:  E ba wa korin po...


6.  lfe l'akoja ofin

     Baba fun wa n'ife

     Ki agba feran omode 

     At’okunrin at'obirin, 

     Ife l’awon Angeli

     Fi nyin Baba loke.

Egbe:  E ba wa korin po...


7.  lwe Woli Joel

     Ni ori ekeji 

     Ese ekejidinlogbon 

     Ase na se si Kerubu 

     Ati Serafu loni,

     Ni arin Egbe wa. 

Egbe:  E ba wa korin po...


8.  Ogo ni fun Baba

     Ogo ni fun Omo

     Ogo ni fun Emi Mimo 

     Ogo ni f ’Olodumare

     ‘Wo ni Serafu nwo

     Ma je k’oju, ti wa.

Egbe:  E ba wa korin po,

           K’awa jumo k'AIleluya 

           Ope to ye fun Jehovah 

           Oba Onibu-Ore.  Amin

English »

Update Hymn