HYMN 138

(FE 155)
“lba mase pe Oluwa ti o ti wa ni tiwa” 
- Ps. 124:1



1.  lBASE p’Oluwa

     Ko ti wa ni tiwa

     Lo ye k’awa ma wi 

     Nigbat’ese gbogun tiwa. 

Egbe:  Ope ni f'Oluwa

           Oba wa Olore

           A ke kabiyesi

           A f'ope fun Jehofa

          T'o gba wa Iowo ota,

          A dupe Oluwu.


2.  Nwon ‘ba bo wa mole 

     Pelu agbara won,

     Ope ni f ’Oluwa,

     Ti ko jeki t’esu bori.

Egbe:  Ope ni f'Oluwa...


3.  Okan wa yo b'eiye 

     Nin' okun apeiye 

     Okun ja, awa yo,

     E yo Jesu da wa sile.

Egbe:  Ope ni f'Oluwa...


4.  Tire ni Oluwa 

     Lati gbe wa leke 

     Gbogbo awon ota, 

     T'o wu ko tile yi wa ka.

Egbe:  Ope ni f'Oluwa...


5.  Ara f ’okan bale

     Sodo Olugbala

     B’esu ti gbon to ni,

     Ko to kini kan fun Jesu.

Egbe:  Ope ni f'Oluwa...


6.  Iranlowo wa mbe 

     L'Oruko Oluwa

     T’O d’orun on aiye 

     Oba awon eni Mimo.

Egbe:  Ope ni f'Oluwa...


7.  Ogo fun Baba wa,

     Ogo fun Omo Re,

     Ogo f’Emi Mimo 

     Metalokan jo gbo tiwa.

Egbe:  Ope ni f'Oluwa

           Oba wa Olore

           A ke kabiyesi

           A f'ope fun Jehofa

          T'o gba wa Iowo ota,

          A dupe Oluwu.  Amin

English »

Update Hymn