HYMN 133

(FE 150)
"Gbe Oluwa ka iwaju re 
nigbagbo" - Ps. 16:8



1.  KO su wa lati ma ko orinti igbani 

     Ogo f'Olorun Aleluya!

     A le fi igbagbo korin na s'oke kikan 

     Ogo f’Olorun, Aleluya!

Egbe:  Omo Olorun ni eto lati ma bu s'ayo

            Pe ona yi nye wa si

            Okan wa ns'aferi Re:

            Nigb’o se a o de afin Oba wa ologo

            Ogo f'Olorun, Aleluya!


2.  Awa mbe n'nu ibu ife t'o ra wa pada 

    Ogo f'Olorun Aleluya!

    Awa y'o fi iye goke lo s‘oke orun 

    Ogo f‘Olorun, Aleluya!

Egbe:  Omo Olorun ni eto...


3.  Awa nlo si afin kan ti a fi wura ko 

    Ogo f’Olorun Aleluya!

    Nibiti ao ri Oba ogo n’nu ewa Re 

    Ogo f’Olorun, Aleluya!

Egbe:  Omo Olorun ni eto...


4.  Nibe ao korin titun t’anu t‘O da 

     wa nde

     Ogo f’Olorun Aleluya!

     Nibe awon ayanfe yo korin ‘yin 

     ti Krist;

     Ogo f’Olorun, Aleluya!

Egbe:  Omo Olorun ni eto lati ma bu s'ayo

            Pe ona yi nye wa si

            Okan wa ns'aferi Re:

            Nigb’o se a o de afin Oba wa ologo

            Ogo f'Olorun, Aleluya!  Amin

English »

Update Hymn