HYMN 132

(FE 149)
“Emi o yin O tinutinu mi gbogbo"
 -Ps.138:1


1.  ENYIN Angel orun ebu sayo 

     Kerubu Serafu aiye gberin 

     K’awa ko ke Hosanna

     Ka si foribale fun 

     Metalokan Olore. 

Egbe:  Ka jo ho, Ka jo yo 

           Nitori Baba pe wa sinu agbo 

           Ka jo ho, ka jo yo

           Ka si le n'iwa mimo 

           Ti y'o mu wa de Kenaan.


2.  A dupe t'Olorun wa pelu wa, 

     A dupe pe Michael je ti wa 

     E je ka jo damuso

     Ka si yin Baba loke

     Ti O da wa si d'oni. 

Egbe:  Ka jo ho, Ka jo yo...


3.  Oluso-Agutan Israeli,

     lwo ti ki sun, ti ki togbe 

     Masai fi opa Re to 

     Awon to sun ninu wa 

     K‘ife Re ko le ma tan. 

Egbe:  Ka jo ho, Ka jo yo...


4.  Baba, masai se wa l‘agutan Re, 

     Ti yio ma gbo ipe Oluwa Re, 

     Ma je ka sonu kuro

     Ninu ona toro na

     Ti o lo si ibi iye.

Egbe:  Ka jo ho, Ka jo yo...


5.  Alabukunfun n'lwo eniti

     O npese fun awon eni igbani 

     Jowo masai be wa wo,

     Pelu ebun rere Re,

     K’awa le sin O dopin.

Egbe:  Ka jo ho, Ka jo yo 

           Nitori Baba pe wa sinu agbo 

           Ka jo ho, ka jo yo

           Ka si le n'iwa mimo 

           Ti y'o mu wa de Kenaan.  Amin

English »

Update Hymn