HYMN 122

Tune: CM



1.  OLORUN Olodumare 

     Baba, Omo, Emi 

     Riri Eni t’a ko le mo 

     Eni t’a ko le ri.


2.  Ye! Baba Olodumare 

     K'a wariri fun O

     Ni gbogbo orile-ede 

     Li a o ma sin O.


3.  Olorun Omo, Ore wa

     “Wo t'o ra wa pada 

     Ma jowo wa, Olugbala 

     Gba wa patapata.


4.  A! Olorun Emi Mimo 

     Wo Olore-Ofe

     A be O, fun wa ni imo

     K’a m’Olorun n’ife.


5.  Okansoso sugbon meta 

     Eni Metalokan

     Olorun awamaridi 
 
     Eni Metalokan.  Amin

English »

Update Hymn