HYMN 121

1.  F'ORUK' Olorun loke 

     T’O l'agbara at’ola 

     Olorun ibi gbogbo 

     N'iyin ati ogo wa


2.  F‘oruko Krist’ Oluwa 

     Om’ Olorun ti a bi

     Krist’ t’O da ohun gbogbo 

     Ni k'a san ‘yin ailopin.


3.  F'Olorun Emi Mimo 

     Ni k’iyin pipe wa lae 

     Pelu baba at’Omo 

     Okan l’oruko, l’ogo.


4.  Orin t'a ti ko koja

     T’ao si ma ko lae leyi

     Ki awon iran ti mbo 

     Dapo korin didun na.  Amin

English »

Update Hymn