HYMN 12

C.M.S 22, H.C 6.8s (FE 29)
“Oluwa yio je imole ainipekun 
fun O" - Isa 60:20


1.  JESU, bukun wa k’a to lo

Gbin oro Re si okan wa;

K’o si mu k’ife gbigbona 

Kun okan ilowowo wa, 

Egbe:  Nigba iye at’iku wa 

Jesu, jare se’ mole wa.


2.  Ile ti su, orunti wo, 

'Wo si ti siro iwa wa

Die n'isegun wa loni 

Isubu wa lo papoju 

Egbe:  Nigba iye ati...


3.  Jesu dariji wa: fun wa 

L‘ayo ati eru mimo 

At‘okan ti ko l'abawon 

K'a ba le jo O l’ajotan: 

Egbe:  Nigba iye ati...


4.  Lala dun ‘tri lwo se ri 

Aniyan fere, O se ri:

Ma je k'a gbo t'ara nikan 

K‘a ma bo sinu idanwo, 

Egbe:  Nigba iye ati...


5.  A mbe O f'awon alaini, 

F'elese at' awon t'a fe,

Je ki anu Re mu wa yo,

'Wo Jesu, l‘ohun gbogbo wa, 

Egbe:  Nigba iye ati...


6.  Jesu, bukun wa, - ile su; 

Tikalare wa ba wa gbe 

Angeli rere nso ile wa;

A tun f'ojo kan sunmo O 

Egbe:  Nigba iye ati...  Amin

English »

Update Hymn