HYMN 119

H.C. 562, C.M. (FE 136)
"On I’Oluwa awon Oluwa, at’Oba
awon oba" - Ifihan 17:14



1.  GBOGBO aiye, gbe Jesu ga, 

     Angeli, e wole fun

     E mu ade Oba Re wa, 

     Se l'Oba awon Oba.


2.  E se l’Oba enyin Martyr 

     Ti npe ni pepe Re 

     Gbe gbongbon-igi Jesse ga 

     Se l‘Oba awon oba.


3.  Enyin iru-omo Israel 

     Ti a ti rapada

     E ki enit’o gba nyin la, 

     Se l’Oba awon Oba.


4.  Gbogbo enia elese

     Ranti ‘banuje nyin

     E te ‘kogun nyin s'ese Re

     Se l'Oba awon oba.


5.  Ki gbogbo orile-ede

     Ni gbogbo agbaiye

     Ki nwon ki, “Kabiyesile” 

     Se l’Oba awon oba.


6.  A ba le pel'awon t’orun 

     Lati ma juba Re

     K'a ba le jo jumo Korin 

     Se l’Oba awon oba.  Amin

English »

Update Hymn