HYMN 118

C.M.S. 563, S.O. ED D7s (FE 135)
"Iwo ki ise eru mo, Iwo di arole
Olorun nipase Kristi" - Gal. 4:7



1.  EWE ti Oba orun,

     Korin didun be ti nlo 

     Korin ‘yin Olugbala 

     Ologo ‘nu ise Re.

Egbe:  A nlo ‘le sodo Olorun 

           Lona t'awon Baba rin 

           Nwon si nyo: nisisiyi 

           Ayo won l'awa o ri.


2.  A nlo sodo Olorun 

    Lona t'awon Baba rin  

    Nwon si nyo: nisisiyi,  

    Ayo won l'awa o ri.

Egbe:  A nlo ‘le sodo...

3.  Korin agbo kekere

     E o simi n'ite Re, 

     ‘Bit'a pese 'joko nyin 

     Ibe si n'ijoba nyin. 

Egbe:  A nlo ‘le sodo...


4.  W'Oke, omo imole 

     Ilu Sion wa lokan 

     Ibe n‘ile wa titi;

     Ibe l'ao r'Oluwa. 

Egbe:  A nlo ‘le sodo...


5.  Kerubu, tesiwaju 

     Serafu, ma jafara 

     Kristi Omo Baba nwi 

     Pe laifoiya ka ma lo. 

Egbe:  A nlo ‘le sodo...


6.  Jesu, a nlo l'ase Re, 

     A ko‘hun gbogbo sile 

     lwo ma j‘ amona wa, 

     A o si ma ba o lo.

Egbe:  A nlo ‘le sodo...


7.  A f’ogo fun Baba wa, 

     A f'ogo fun Omo Re; 

     Ogo ni f’Emi Mimo, 

     Mu wa de ‘le ayo na.

Egbe:  A nlo ‘le sodo Olorun 

           Lona t'awon Baba rin 

           Nwon si nyo: nisisiyi 

           Ayo won l'awa o ri.  Amen

English »

Update Hymn