HYMN 117

H.C. 579, t.H.C. 123, 10s 11s
"Oluwa Olorun mi, Iwo tobi jojo" 
Ps.104:1 (FE 134)


1.  E wole f'Oba Ologo julo

     E korin ipa ati ile Re,

     Alabo wa ni‘Eni lgbanis,

     O ngbe anu ogo, Eleru ni iyin.


2.  E so t’ipa Re, e so t'ore Re 

     Mole l'aso Re, kobi Re, Orun 

     Ara ti nsan ni keke ‘binu Re je

     Ipa ona Re ni a ko sile mo.


3.  Aiye yi pelu ekun yanu re, 

    Olorun, agbara Re l'o da won 

    O fi idi re mule, ko si le yi,

    O si f'okun se aso igunwa Re.


4.  Enu ha le so ti itoju Re? 

     Ninu afefe, ninu imole

     Itoju Re wa nin' odo t‘o nsan 

     O si wa ninu iri ati ojo.


5.  Awa erupe, aw‘alailera,

     ‘Wo l'a gbekele, O ki o da ni 

     Anu Re ronu, o si le de opin 

     Eleda, Alabo, Olugbala wa


6.  ‘Wo Alagbara, Onife julo 

     B‘awon angeli ti nyin O loke

     Be l’awa eda Re, niwon t'a le se, 

     A o ma juba Re, a o ma yin O.  Amin

English »

Update Hymn