HYMN 114

H.C. 567. t.H.C. 520 C.M (FE)
"Emi o ma fi ibukun fun Oluwa
nigbagbogbo" - Ps. 34:1



1.  N‘NU gbogbo ayida aiye

     Ayo on wahala

     lyin Olorun ni y'o ma 

     Wa l'enu mi titi.


2.  Em‘o yangan ti segun Re 

     Tit'awon t'eru npa

     Y‘o fi mi se awokose

     Ti banuje y‘o tan.


3.  Gbe Oluwa ga pelu mi,

     Ba mi gb'Oko Re ga

     N'nu wahala. ‘gba mo kepe 

     O si yo mi kuro.


4.  Ogun Olorun wa yika 

     lbugbe oloto;

     Eniti o ba gbekele 

     Yio si ri ‘gbala.


5.  Sa dan ife Re wo lekan 

     Gbana ‘wo o mo pe 

     Awon t‘o di oto Re mu 

     Nikan l’eni 'bukun.


6.  E beru Re, enyin mimo, 

     Eru miran ko si,

     Sa je ki 'sin Re j‘ayo nyin, 

     On y'o ma toju nyin.  Amin
 

English »

Update Hymn