HYMN 111

C.M.S 550 t.H.C.54 L.M (FE 128)
"E fi yin fun Oluwa" Ps. 146:1



1.  EJE k’a yin Olorun wa, 

     Enit' O wa l’oke orun

     T'O fi onje fun enia 

     Ti O si fi fun eranko.


2.  O si te oju orun lo

     O da orun on osupa,

     lse owo Re n‘irawo 

     lye won awa ko le ka.


3.  O si da ara enia,

     O si fun won lemi pelu 

     O si da ni daradara,

     Bi o ti ye, bi ba ti wa.


4.  Sugbon enia dibaje 

     Nwon si bo sinu buburu 

     Ere ese ni nwon si nje 

     Ni wahala ati n’iku.


5.  Sugbon je ka yin Olorun

     On fun wa ni Kristi Jesu

     Lati wa awon t'o ti nu

     Ninu ese ti nwon ti nrin.  Amin

English »

Update Hymn