HYMN 109

(FE 126) Ki a fi ope fun Oluwa
Tune: K’a fi ope fun Olorun wa



1.  K'A fi ope fun Oluwa

     fun gbogbo opo anu Re

     K'a wa di ihamora wa

     Lati b’esu jagun.
 
Egbe:  Esu n’ipe sugbon a o segun

            Ni agbara metalokan

            Ileri ti Oluwa se

            Y‘o wa sibe titi.


2.  Gbogbo aiye e ho f’ayo

     Ki gbogbo wa si kun fun ‘se

     Ki aja titi de opin

     K’a si fi ‘da le le.

Egbe:  Lese Kristi omo Baba

           Ni ibi awon Angeli nyo

           K’a be won yin Baba loke

           Omo, Emi lailai.


3.  Awa omo egbe Serafu

     A fi ogo fun Oluwa

     T’o je k’emi tun ri emi

     Ogo f ’oruko Re.

Egbe:  Gb 'oju s 'oke wo asia,

           Fun gbogbo awon t'o segun

           Enyin ara e ku abo,

           Ki Baba pelu nyin.


4.  Awon t’o ti segun saju

     Nwon nwo wa bi awa ti nja

     Nwon si nfi ohun kan wipe

     Ara ma jafara.

Egbe:  Nitor’ akoko die loku

           Ti aiye yi yio koja lo

           Bi asegun o daju pe,

           A o gb’a ade iye.


5.  Awa si tun ki asaju wa,

     Ati awon ‘mo ogun re,

     Ara e ku ise emi,

     K'a gb’owo lowo ara wa.

Egbe:  E ku abo, enyin ku iIe

           K'Olorun pelu gbogbo wa,

           K'o si fi ade ogo Re,

           De gbogbo wa lori.


6.  Ope ni fun Metalokan

     T'o ba wa fo ‘tegun esu,

     Halleluyah‘s Olorun wa,

     Oju ti Lusifa.

Egbe:  Ara e jo pelu ayo,

           Ara e gbe ohun s'oke

           Ki Baba fun wa ni fe Re.

           Eyi ti ko l’egbe.  Amin

English »

Update Hymn