HYMN 108

Tune: Children of Jerusalem



1.  KERUBU ati Serafu

     E fun irugbin rere s‘aiye

     Enyin l’a pe Iati s' awon

     Ti yio pade Oluwa l'oke.

Egbe:  Gbo, gbo, gba b'awon

           Serafu ti nke

           Gbo, gbo, gbo b’awon

           Kerubu ti nke

           Halleluyah, Halleluyah,

           Halleluyah, f’Oba wa.


2.  Onigbagbo, e ji giri,

     K’a fi iwa ese s'ile

     K’a se ife Oluwa wa,

     K'a Ie r'oju rere Olorun.

Egbe:  Gbo, gbo...


3.  Onigbngbo, e gb'adura

     E fi okan funfun sise

     E gb' awe pelu iwa mimo

Egbe:  Gbo, gbo...


4.  Enyin araiye, e tun aiye se

     Fun bibo Jesu Oluwa

     K'ese dinku, k’ajakale aron

     Ma ti wa lo s‘orun apadi.

Egbe:  Gbo, gbo...


5.  Onigbagbo beru Olorun

     Feran Omonikeji re

     Mase pegan mase binu

     Olorun yio gbo adura re.

Egbe:  Gbo, gbo...


6.  Opo idanwo l’o wa l’aiye

     Sugbon eyi t’o buruju

     K’a ma r’owo, k’aisan de ni

     JAH jowo ma fi eyi se wa.

Egbe:  Gbo, gbo, gba b'awon

           Serafu ti nke

           Gbo, gbo, gbo b’awon

           Kerubu ti nke

           Halleluyah, Halleluyah,

           Halleluyah, f’Oba wa.  Amin

English »

Update Hymn