HYMN 107

8.7.8.7 D



1.  GBO orin 'yin dida aye

     T’egberun orile nko

     Orin didun bi t'angeli

     O ndun bi omi pupo

     'Bukun, ogo, ipa gbala

     Fun Olorun lor‘ite

     Baba, Omo, Emi Mimo

     Olola, lainipekun.


2.  Titi lo, lat‘oro d‘ale

     Lor‘olukuluku ‘le

     Lat‘ opolopo eniyan

     llu alawo pupa

     ‘Lawo dudu t'a da n’ide

     Funfun ti o po niye

    Omnira alarinkiri

    De ‘le awon Arabu.


3.  Lati ebute otutu

     De ile ti o mooru

     Awon olokan gbigbona

     Leba okun Pasifik’

     Lat’opo aimoye okan

     Onigbagbo alayo

     Awon to nsona bibo Re

    Won fere de Sion na.


4.  Akojo orile-ede

     Lat’inu eya ahon

     Gbo, won nkorin iyin titi

     Gbo orin ologo ni

     O b’afonifoji mole

     O si ndun lori oke

     O ndun si waju tit‘o fi

     Kun ibugbe Olorun.


5.  Gbo, didun orin na dapo

     Mo orin awon t’orun,

     Awon t’o koja n‘nu danwo

     Sinu isimi loke

     Won wo aso ailabawon

     Imo ‘segun lowo won

     Won nfi duru ko Hosana.


6.  “Ogo fun Eni t'o fe wa

     T'O we wa n'nu eje Re

     K'oba, alufa, ma korin

     Si Baba, Olorun wa

     K'eeyan mimo on Angeli

     Ko Aleluya titi:

     Asegun orun apadi:

     Olodumare joba."  Amin

English »

Update Hymn