HYMN 103

(FE 120)
Tune: Lo Kede Ayo Na.



1.  OLUWA l’Olus‘agutan mi,

     Emi k’o salani

     O mu mi dubule ‘nu papa oko,

     Tutu minimini.

Egbe:  Awa dupe, at’ope da,

           Fun idasi Re fun wa

           Larin Egbe Serafu.


2.  O mu mi lo si iha omi,

     Idake roro si de,

     O si tu okan mi lara,

     Ni ipa oruko Re.

Egbe:  Awa dupe...


3.  Nitoto bi mo tile nrin

     Larin afonifoji

     Emi ki yio beru ibi kan

     Nitori o wa pelu mi.

Egbe:  Awa dupe...


4.  Ogo Re ati opa Re

     Nwon si ntu mi ninu

     lwo te tabili onje sile

     Ni iwaju mi.

Egbe:  Awa dupe...


5.  Nitoto ire ati anu

     Ni yio ma to mi lehin

     Emi o gbekele Oluwa

     Ni gbogbo ojo aiye mi.

Egbe:  Awa dupe...


6.  K'a f'ogo fun Baba wa loke

     K'a f'ogo fun Omo Re

     K‘a f‘ogo fun O Emi Mimo

     Metalokan l'ope ye.

Egbe:  Awa dupe...  Amin

English »

Update Hymn