HYMN 101

11S A.M.



1.  AIKU, Airi, Olorun ogbon gbogbo

     O ngbe'nu imole, be l'o farasin

     Olubukun julo, A yin oruko Re.


2.  L’aisimi, L'aikanju, O dake roro

     Nin‘oro, l'aosofo, O njoba ni’pa

     Ododo Re ga ju awon oke lo

     Kuuku Re j'orisun ire ati 'fe.


3.  O mbukun fun eniyan, t‘omode,

     t’agba

     lgbe aye ‘rorun l'o fi fun eda

     A ngba bi itannna eweko tutu

     A nwa, ti l’a si nku

     'Wo ko yi pada.


4.  Oba mi Ologo, Mimo ‘nu imole

     Awon angel yin O, won bo oju won

     Awa na y'o yin O, bi awon t'orun

    Ogo imole l‘o pa O mo fun wa.  Amin

English »

Update Hymn