HYMN 100

1.  EMI Baba Alaye

     Sokale pelu

     Agbara Pentikosti

     So okan wa ji

     Ki O si mu gbona

     B'ina orun nla

     Pelu ‘tunu nla

     Tan ‘mole re.


2.  Aye ati emi wa

     Gba, fi se Tire

     Ninu isin wa fun O

     Ka ni ‘ranwo Re

     Lati j'olotito

     K’ebun at‘orun

     Ti Pentikosti

     Ba s'ori wa.


3.  Fi eje ‘yebiye Re

     T'oke Kalfari
 
     We okan ese wa nu

     Si ra wa pada

     Fi ‘fe kun aya wa

     Ka rin ‘na oto

     lfe Re lao se

     Bi ti orun.


4.  Baba, Omo on Emi

     Metalokan lae

     lyin, Ogo, agbara

     Je Tire nikan

     Ewa Re l'aye yi

     Yo je ayo wa

     Pelu idupe

     Aleluya!  Amin.

English »

Update Hymn