HYMN 10

C.M.S 18, H.C 24, t.H.C 99 10s. (FE 27)
"Ngo dide, ngo to Baba mi la" - Luku 15:18


1.  Baba, a tun pade l'oko Jesu,

     A si wa teriba lab‘ese Re;

     A tun fe gb‘ohun wa soke si O, 

     Lati wa anu Iati korin 'yin.


2.  A yin O fun itoju ‘gba gbogbo 

     Ojojumo l'a ma rohin se Re, 

     Wiwa laye wa, anu Re ha ko? 

     Apa Re ki O fi gba ni mora?


3.  O se! a ko ye fun ife nla Re,

     A sako kuro Iodo Re poju 

     Sugbon kikankikan ni O si npe; 

     Nje, a de, a pada wa ‘le, Baba.


4.  Nipa oko t‘o bor‘ohun gbogbo 

     Nipa ife t'o ta 'fe gbogbo yo, 

     Nipa eje ti a ta fun ese,

     Silekun anu, si gbani s'ile.  Amin

English »

Update Hymn