HYMN 1

C.M.S. 1, H.C. 2, L.M. (FE 19) "Emi tikara mi yio ji ni kutukutu" - Ps 108:2 

1. Ji, okan mi, ba orun ji Mura si ise ojo re; Mase ilora, ji kutu, K’o san gbese ebo oro. 

2. Ro gbogbo ojo t‘o fi sofo Bere si rere ‘se loni, Kiyes' irin re laiye yi; K'o si mura d‘ojo nla ni. 3. K’oro re gbogbo j'otito K'okan re mo b‘osan gangan Mo p'Olorun nso ona re O mo ero ikoko re. 

4. Gba ninu imole orun Si tan ‘mole na f'elomi Jeki ogo Olorun re, Han n’nu wa ati ise re. 

5. Ji, gbon‘ra nu ‘ wo okan mi Yan ipo re larin Angel Awon ti nwon nkorin iyin Ni gbogbo oru s’Oba wa. 

6. Mo ji, mo ji, ogun orun Ki isin yi s‘okan mi ji Ki nle lo ojo aye mi Fun Olorun mi bi ti yin. Amin 

English »

Update Hymn